Content pfp
Content
@
0 reply
0 recast
0 reaction

CRYPTLAOAT🎩Ⓜ️🍓🌲🎭 pfp
CRYPTLAOAT🎩Ⓜ️🍓🌲🎭
@laoat
Àìsàn burúkú ni ìbínú jẹ́... Kò dára bẹ́ẹ̀ ni kò sunwọ̀n.... Ìbínú yára pànìyàn... Ìbínú rán ènìyàn lọ sí ibi tí kò tọ́.... Ìbínú kìí tún nǹkan ṣe ó máa ń ba nǹkan jẹ́ ni.... Ohun tí èèyàn ti lé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún... Ìbínú a máa bàájẹ́ ní ọjọ́ kan... Ìbínú a máa lé olóore jìnà síni... Inú bíbí a máa fa wàhálà síni lọ́run... Ọ̀pọ̀ èèyàn ni inú bíbí ti sìn dé ọgbà ẹ̀wọ̀n... Ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó ló ti foríṣọ́pọ́n ní pa inú bíbí Ọ̀pọ̀ obìnrin ló ti lọ dálémoṣú nípasẹ̀ inú bíbí Ọ̀pọ̀ ọkùnrin ló ti di Àpọ́n ọ̀sán gangan ní pa àìsàn inú àbíjù.... Ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ ìjọba ni wọ́n ti fún ní ìwé gbé lé ẹ nípasẹ̀ inú bíbí Ọ̀pọ̀ oníșẹ́ ọwọ́ ló ti lé àwọn oníbáárà ní pa aṣọ ìbínú tí ó gbé wọ̀... SÙÚRÙ KÌÍ PỌ̀JÙ
4 replies
0 recast
1 reaction

OLOFIN 🎩 🎭🌲🍓 pfp
OLOFIN 🎩 🎭🌲🍓
@sunkanmi
+100 🔥 FIRE added. Check your balance.
0 reply
0 recast
0 reaction